Thursday, 11 July 2019

ÀBÙSÓÓLÙ N KÉ! By: Oluwasola Abiola Elisha



Ìgbà kan ò to lo bíi òréré
Ayé ò tó lo bíi òpá ìbon
E so fún jayé-jayé kí ó rora jayé
E so fún lògbàlogbà kí ó rora lògbà
Nítorí wípé kò s'éni tó mò'la
Bí ayé bá n ye ó l'énìí
Tí gbogbo ènìyàn n gba tì re
Rora jayé o
Àwon tó jayé lánàá
Wón wà nínúu kòtò  esè  méfà
Kí ló  wá  dé
Kí ló n se wá
Tí  a n fi whàálà  wá owó
Tí  a n fi ipá  wá orò
Tí  a n dá  ra  wa lóró nítorí owó
Tí  a n se ara wa níkà nítorí ipò
E ò se je kí gbogbo wa o tera mó sé
Kí a yan òtító síso láàyò
Kí a fi inú kan bárawa gbe
Kí ìlosíwájú leè dé bá gbogbo wa ni t'ako t'abo

Èyí ni igbe tí  Àbùsóólù n ke  tantan

ABSOL - 07032277508

©ABSOL

1 comment:

  1. Igba 'lonigba nka,
    Igba Kan ko kolole aye gbo,
    Bo ba jaye titi, ranti ese mefa

    ReplyDelete